Header Ads

Sebótimọ Ẹlẹ́wà Sàpọ́n - Ó ń rọ̀ wá láti máse kọjá agbára wa

  • Awọn obinrin to n se ounjẹ
Image copyrightAFP

Oniruuru owe ati asamọ lo wa nilẹ Yoruba eyi ti wọn maa n parọwa fun wa, kọ wa lọgbọn, fun wa loye, to si tun maa n tọ wa sọna ninu igbe aye wa lojoojumọ.

Ọkan lara awọn owe to n parọwa fun wa ni "Ṣebotimọ Ẹlẹwa Sapọn", awọn ohun to si yẹ ka mọ nipa owe naa ree:

Itan nipa owe ‘Sebótimọ Ẹlẹwa Ṣàpọ́n

Obinrin kan wa nilu Abẹokuta to nta ẹwa sise ni adugbo Sàpọ́n nilu Abẹokuta, tii se olu ilu nipinlẹ Ogun bayii.

Obinrin ẹlẹwa yii mọ ounjẹ naa se debi pe awọn eeyan maa n pe biba sọdọ rẹ lati du ẹwa rẹ ra ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Media captionTọkọ-taya Aràrá: Àwọn èèyàn máa ń wò wá, ta bá fa ọwọ́ ara wa ní títì

Agbada ikoko nla kan lo maa fi n se ẹwa fun tita, to si n jẹ ere rẹpẹtẹ nibẹ lojoojumọ.

Koda, nibi ti ẹwa rẹ dun, to si tun jẹ itẹwọgba de, awọn onibara rẹ maa n ra ounjẹ naa ni awin, lai sanwo ti owo ba sa fẹrẹ lapo wọn.

Nigba to ya, oju aanu n pa obinrin ẹlẹwa yii ku lọ, tori ọpọ gbese tawọn eeyan jẹ ẹ, ko jẹ ko ri owo ta ọja mọ, ti odiwọn ikoko ẹwa to n se si n din ku lojoojumọ.

Niwọn igba to si jẹ pe alatise ni yoo mọ atise ara rẹ, eyi lo mu ki ẹlẹwa Ṣapọn da ọgbọn ti awọn onibara rẹ ko fi ni gba igba lori rẹ, nipa rira ọja rẹ lawin.

Ti onibara kan ba si tọ obinrin naa wa pe oun fẹ ra ẹwa sise rẹ ni awin, iya ẹlẹwa yii yoo sọ fun pe ko ma ra ẹwa lawin, se ni ko ra iye ẹwa ti owo rẹ ka lai jẹ gbese.

obinrin kan n fẹ ina igiImage copyright@IRDAFRIKA

Esi to si saba maa nfọ jade fun wọn, lati rọ wọn ki mase ra ẹwa lawin ni pe "Ṣe bo ti mọ", eyi to tumọ si pe mase ra kọja iye owo too ni lapo bayii.

Bi ọjọ se n gori ọjọ, ti osu si n gori osu, lawọn eeyan ba sọ di owe ati asa obinrin ẹlẹwa naa. Ki wọn si to beere ọja awin lọwọ rẹ, ni wọn ti mọ esi ti yoo fi da wọn lohun.

Ọrọ yii si ni wọn fi maa n sa obinrin naa pe "Ṣe bo ti mọ, Ẹlẹwa Ṣapọn". Diẹ-diẹ si ni owe naa gbilẹ, to si di itẹwọgba titi di oni.

Itumọ owe yii lo si n parọwa si ẹni kọọkan wa pe ka ma se kọja agbara wa, ka maa se ohun gbogbo ni iwọntun wọnsi, iwọn eku ni iwọn itẹ, ka maa baa maa jẹ gbese kiri, eyi to lee mu itiju ati ipaya de ba ni.

Ta ni Ẹlẹwa Ṣapọn?

  • Orukọ ẹlẹwa Ṣapọn ni Amudat Janeth Ewusi Ọdẹsọla
  • Ọdun 1925 ni wọn bi ẹlẹwa Ṣapọn sile aye
  • Ile ẹkọ alakọbẹrẹ Methodist to wa ni adugbo Ijoko nilu Abẹokuta lo lọ, ko to bẹrẹ owo sise
  • Ẹwa lo n ta tẹlẹ ko to maa se ẹwa ta lọdun 1951
  • Tọba-tijoye, olowo ati mẹkunnu lo maa n ra ẹwa sise rẹ fun jijẹ
  • Ọdun 1995 lo dawọ okoowo ẹwa tita duro lẹyin to ti ta ẹwa ni adugbo Ṣapọn fun ọdun mẹrinlelogoji
  • Nkan ko daa to fun obinrin yii lasiko naa, to si ta ile kan soso to ni, ni ẹgbẹrun lọna ogun naira lọdun 1994, to si lọya ile gbe
  • Lọdun 2013, nigba ti obinrin naa wa lẹni ọdun mejidinlaadọrun, o n beere fun iranwọ awọn oninure, ko to lee sanwo itọju nile iwosan, ko si tun ri ọwọ mu lọ sẹnu.

No comments

Copyright 2017. Powered by Blogger.